EWÉ OJÚ OMI

Author: AbdulKareem Ajimatanraeje

Ojúoró nií lékè omi,
Osíbàtà nií lékè odò.
À’tojú oró àtòsíbàtà,
Omi níí daríi dede wọn,
Ewé ojú omi ni dede wọ́n jẹ́.
Omi l’ojúoró fií sọlá,
Odò l’òsíbàtà fií se fújà.
̀Ọ̀tọ̀ n tọ́lú, ọ̀tọ̀ n tọ̀lú,
Ìpín ò jọra wọn pín-ìn pìn-ìn,
L’àwọn kan fií jólórí,
T’áwọn kàn fií jọ́mọlẹ́yìn.
Kólórí ó má joyè olè,
Bámú bámú ni mo yó,
kó rańtí ọmọ báàní-à-tọọrọ,
Kó rańtí ọmọ báàní-à-béèrè.
Kòlà kòsagbe ń bẹ láàrin wa,
Kòsíbi tí wọn kò sí l’órílẹ̀,
Adẹ́dàá ti dáwa pé,
L’élétí méjì péré,
Ká yáa yárawa lọ́pọlọ pípé,
Nítorí kále gbọ́rọ̀ yékéyéké,
L’etí wa se pé méjì pépé,
Nítorí kàle sọ̀rọ̀ níwọ̀n,
L’ẹnu wà se mọ níwọ̀n.
Ẹ farabalẹ̀ kí ẹ gbọ́ díẹ̀ lọ́rọ̀,
Ojùuyín ò ojú àwa ni.

Etí wa la fi gbóhun tẹ́ẹ wí fáráyé.
Tọkàn-tọkàn la fi tán-an yín,
Ọwọ́ wa la fi yàn yín sípò.
Ẹnu àìmẹ́nu, ètè àìmétè, ló k’ọ́ràn bẹ́rẹ̀kẹ́ ẹ yín.
Èsùró pàdídà tán, òsèlú ń jẹ̀lú,
Adaranjẹ̀ ń darán jẹ̀lú,
Ẹni a gbójú okùn lé ò jẹni agba.
Ẹni a fọkàn tán ti jáwa ní tàn-àn mọ́ ọ̀.
Kí wọn ó fẹ́ni lójú, ata ni wọ́n fi sẹ́nu.
Kí wọn ó tini lẹ́yìn, ẹ̀gún ni wọ́n fi s’ọ́wọ́.

Wọ́n fìyà jẹwá, wọn fátẹ́gùn síwa,
Bí ò bá rí bẹ́ẹ̀,
Ó ń jọ bẹ́ẹ̀ náàni.
Eégún atiro wọlé,
Ènìyàn atiro jáde,
Olówó ń lówó lọ́wọ́,
Talakà ń tálákuta,
A ò ní sépè mọ́ láyé, ẹnu wa ò ní gbófo.
Olósèlú tí ń jẹ̀lú,
Tí ǹ fẹ̀tọ́ aráàlú dùnlú,
Olórí tó jolórí tán, tí ó tún fẹ́ máa jẹ̀lú.

Sebí wọn ò kíí jẹ méjì lábà.
Gbogbo ibi wọ̀n bá wọkọ̀ dé,
Gbogbo ibẹ̀ ni wọn ó fẹsẹ̀ rìn dé.
Gbogbo ibi wọ́n bá náwó ìlú dé,
Gbogbo ibẹ̀ ni wọ́n ó tọọrọ báárà dé.
Wọn ò ní kú, wọn ò ní rùn,
Wọ́n á jọ ẹyẹ àparò, wọ́n ó kàn ma pọ́n làsọ ni.
Wọn ò ní kú, wọn ò ní rùn,
Wọ́n à j’ọ̀jàpá mọ́pọ̀lọ́,
Ara wọn ò ní jọ̀lọ̀.
Wọn ò ní kú, wọn ò ní rùn,
Àsàdànù l’ọmọdé ń sàkúta.
kín-ín-ni yínmí yínmí ń fọsẹ se ná?
Òfooooooo!
Kín-ín-ni alákàn ń fepó se gan?
Òfò!
Kín-ín-ni alántakùn ń fòwú rán ná?
Òfoooooooo!
Kín-ín-ni ọ̀pọ̀lọ́ ń f’ìlẹ̀kẹ̀ se gan?
Òfò!
A ò kúkú ní sépè, ọ̀rọ̀ ń jáde àsé ń tẹ̀le ni.
Ẹ fẹ̀tàn gba tọwọ́ aráàlú tán,
Ẹ rẹ́wa jẹ tán,
Ẹ tún fẹ́ ma rẹ́wa tà lọ́jà.
Ẹ̀ ń jẹwó wa mọ́ tiyín,
Májèlé lẹ̀ ń jẹ ẹ ò mọ̀.
Pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ tí a nà ní pòpá,
Ẹní bá ta bà kó má sè bínú,
Kó jọ̀wọ́, kó tún bẹ̀ se ni.
Akéwì ń kéwì,
Ó ń  fewì í kìwà ìkìlọ̀ọ̀ọ̀ọ̀

••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••
ÀÀRẸ ÀGBÀ
ABDULKAREEM AJÍMÁTÀNRAẸ̀JẸ
IFÁFITÌ ỌLÁBÍSÍ ỌNÀBÁNJỌ
08084088272 Karjelly2@gmail.com

Advertisements

TO MEET A GOAL

By Wasiu Owolabi

I discovered some things
On which I need to work

Had many opportunities
But didn’t utilize to check

And balance my discoveries
Then draw clearly, my mark

The last of opportunities
Is this, some voices bark

I have to go mining the coal
For I have to meet a goal

~OWO

image