ADARAJÈLÚ

By:
Ààrẹ Abdulkareem Ajimatanraeje
Ifáfitì Ọlábíśí ọnàbánjọ
Karjelly2@yahoo.com
_____________________________________
Wọ́n ní a gbádé f’áládé,
A gbádé f’áládé.
Wọ́n ní a gbóyè f’ólóyè,
A gbóyè f’ólóyè.
A móyè yí jẹ,
Ìwo n pápá, ìwo n nà.
Ká róyè se,
Ó sọ̀gá a ká róyè jẹ.
B’íyọ̀ ti ń sọ̀gá l’áwùjọ èèpẹ̀,
T’óyin ń sọ̀gá l’áwùjọ adùn,
Bẹ́ẹ̀ l’adé ń sọ̀gá l’áwùjọ fìlà.
Ọ̀pọ̀ olórí nílẹ̀ ẹ wa yìí,
La fi ń dí gẹrẹwu.
Ká f’èèyan joyè àwòdì,
Kó má le è gbé bébà,
Dèpò dépò adìẹ.
Olórí kìí s’ohun à á jàá sí
Sebí ipò ẹlẹgẹ́ náà ni.
Ẹ jẹ́ kà t’ibi pẹlẹbẹ,
Ká fi mú òlẹ̀lẹ̀ jẹ
Bí ẹ bá r’ọ́mọ fúlàní,
Tì ń f’òpá kan dagba màálù,
Eré e pá kọ́ ló se débẹ̀ o, ẹ ò mọ̀.
Irú olórí wo lèyí ná,
Adaran mọ́ dàáràn,
Adaranjẹ̀ tí ń daranjẹ̀lú.
Ẹ̀yin olórí ìlú wa wọ̀n yí,
Kí ẹ tó dépò tí ẹ wà yí ná,
Màá dirú màá digba,
Màá kẹ́rú, màá kẹ́rù,
Òun lè ń gbé pòyì ẹnu.
Wọ́n dórí oyè tan,
Ijó titun ló bọ́ sí wọ́n lẹ́sẹ̀.
Orin titun ló bọ́ sí wọ́n lẹ́nu.
Máa jó lọ mò ń wẹ̀yìn n làkọ́kọ́,
Bámúbámú ni mo yó n’ìkẹyìn.
Akìi jẹ méjì lábà,
Akìi j’olórí tán ká tún ma jẹ̀lú.
Ẹ̀yin olórí ìlu wa yìí,
Ẹ latí inú yín bẹ̀lẹ̀njẹ́.
Kókóókó làá rán fá adití,
Kẹ́kẹ́ẹ́kẹ́ ni wọn lu kòso,
Gúdúgúdú ni wọn lu àrán òsà,
Pakájá pakájà n làá gbóhùn bàtá.
Olórí k’ólórí nílẹ̀ wa yìí,
Olóyè k’ólóyè nílẹ̀ wa yìí,
Tó fẹ̀tàn gba tọwọ́ aráàlú tán,
To fáwa lórí fọ̀dà kùn ún,
Tó fi kóngo wọn gàrí ìyà,
Tó folódó w’èlùbọ́ ìsẹ́,
̀Tó fi dìríkà wọ̀n rẹsì òfò,
K’ọ́mọ ìlú tó mẹ̀tọ́,
Mọ gba ohun tí ò lẹ́tọ̀ọ́,
L’ọ́wọ́ ẹnití ò tọ́.
Rìbádùn ò n kò gba rìbá,
Mọ fọwọ́ ẹ̀yìn gba rìbá,
Nítorí bóo bá jìyà tań,
Ọọ́ọ̀ tún jewé iyá mọ,
Ọba à mi o lù sẹ́gun,
Ọba à mi á sanjọ́,
F’áfagbádá kówóòlú,
F’áfikakí kọ́rọ̀ mọ́lẹ̀.
Àtẹnífẹ́ mọ̀wá mọ́dù,
Àtẹnífẹ́ mọ̀wá mọ̀lú,
Gbogbo rè náà ló pójú owó,
Àgbà tó ròfọ́ ìkà,
Ọmọ rẹ̀ á jẹ níbẹ̀ dandan.

Advertisements

Leave a Reply

Fill in your details below or click an icon to log in:

WordPress.com Logo

You are commenting using your WordPress.com account. Log Out /  Change )

Google photo

You are commenting using your Google account. Log Out /  Change )

Twitter picture

You are commenting using your Twitter account. Log Out /  Change )

Facebook photo

You are commenting using your Facebook account. Log Out /  Change )

Connecting to %s

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.