ÌPÀDÉ ÒBÍ ÀTI OLÙKỌ́

Author: Abdulkareem Ajimatanraeje

Eku wẹ́ẹ́rẹ́wẹ́ ní ń dalé rú.
Àrò wọ̀ọ̀rọ̀kọ̀ ní ń dọbẹ̀ nu.
Èèmọ̀ lukutu pẹ́bẹ́ ǹ pẹ̀bẹ́ wọlé dé,
Ẹ jẹ́ kájọ fetí inú wa gbọ.
Taló fẹ́ fọmọ odó tayín ná?
Taló fẹ́ f’àkàbà tan-an ná òsùpá gan?
Ẹ̀fọn ń t’ẹfọ̀n láyà.
Èkúté fẹ́ f’imú Ológbò fọn fèèrè.
Èsùró pàdí dà,
Èrá mọ̀ ń kilẹ̀,
Pàkúté ré péké,
Òkété ló mú pàkúté,
L’ókété bá ń r̀ed́i bí òréke.
̀Àdán ò s’eku s’eye
Àdán a b’éku rẹ́,
Àdán a b’ẹ́yẹ dọ́gba,
Agbọ́tẹnu eku wí f’ẹ́yẹ,
Agbọ́tẹnu ẹyẹ wí f’éku,
Asọ̀besèlú láàrín ọ̀tá méjì.
Àrà méè rírí lèyí o.
Bí túbọ̀mí bá pọ̀ jurun orí,
Sebí lórí apárí ni,
Bí gbogbo ara bá jẹ́ kìkì ewú,
A jẹ́ lára àfín lówà.
Túlẹ̀ ti ń forí túlé agbọ́n tipẹ́,
Wọ́n ti sọwá digbá ìkólẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Olórí ẹ̀kọ́ tún gbéwa léwọn lọ́wọ́,
Àwọn túlẹ̀ ń dárà n’ílẹ̀yí,
Ẹ máa tẹ́tí gbọ́ ohun tí wọ́n ti dá sílẹ̀ lọ́ràn.
Bójú akátá bá léwó,
Sẹ́nu adìẹ ló tọ́ sí,
B’íyẹ̀pẹ̀ bá wọnú ìrẹsì,
Só tọ́ lẹ́nu asagbejẹun.
Wọ́n gbéwọn gẹsin ááyán,
Àwọn náà ń s’ọ̀pàkọ́ lùkẹ́,
Wọ́n sạpá bí itan,
Wọ́n sàyà bí òkè.
Wọ́n kẹ̀sùn léwa lọ́wọ́, ọwọ́ wa bọ́,
Wọ́n kẹ̀sùn léwa lẹ́sẹ̀, ẹsẹ̀ wọ́lẹ̀.
Wọ́n l’ólódo ni tísà wa,
Kò mèèbó kòle fèèbó.
Kò leè kọ́ni nísẹ́ kámọ̀.
Sebí b’ọ́mọdé bá lásọ bí àgbà.
Kòlè ní àkísà bí àgbà ni mò ń gbọ́,
Ìjà èmi àti túlẹ̀ ò leè tán láyé,
Àdàbi bí mo bá dán rú è wò lókù.
Bí a bá fi kóńdó l’ọ́daràn lọ́wọ́,
Ó kúkú́ le lùyá ẹ̀ pa.
Ọmọ tí a f’owó tọ́ tí ò yinwó,
Ọmọ tí a kọ́ lẹ̀kọ́ tí ò gbẹ̀kọ́,
Ọmọ tó yẹ ó kọ́sẹ́ tẹní ó kàwé dandan.
Wọ́n n’ídàmú olùkọ́ pọ̀ l’ápọ̀jù,
Ojoojúmọ́ igi ni wọ́n yọ síwa,
Nítorí isẹ́ àmúrelé lásán.
Wọ́n sì leè tawá l’ọ́fà,
Bí a bá j’ẹ̀wà ìdánwò.
Bí a bá pẹ́ wọlé ogun ni.
Bí a tún sá jáde ọ̀ràn.
Ìran àgbà wá búra,
Ẹ̀yin àgbà wá búra,
B’éwe ò bá seyín rí.
Sebí eré ipá ní múni j’arunpá,
Áyán k’áyán ń soge lójú àkùkọ,
Èrà kéèrà ń rèdí lójú ọmọńlé.
Ẹ̀yin náà mọ̀mọ̀ kọ́ o,
Ọ̀gá ń pọ̀n yín lẹ́yìn,
Ẹ̀yin náà sì ń fẹyín,
Ẹ ò mọ̀ pówó baba yíun lọ̀gá fẹ́ gbà.
Àlùwàlá ológbò ń kọ́?
Se b’ọ́gbọ́n àti k’ẹ́ran jẹ ni.
Ẹ̀yin òbí ẹ sún mọ́bí,
Ẹ jẹ́ á s’èpàdé òbí àtolùkọ́,
Nìtorí ọ̀rọ̀ tí ń bẹ nílẹ̀ yí.
Àtàrí àjànàkú ni kìí sẹrù ọmọdé.
Oríi màálù ni kìí sẹrù ipọn.
Àjànàkú kọjá rírù, Erín kọjá wíwọ́ ́ọ̣óọ́
Ọmọ tí yò bá j’ásàmú,
Yóó mọ̀mọ̀ sẹnu rẹ̀ sámú.
Ilé la ti ń kẹ̀sọ́ ròòde,
Àbọ̀ ọ̀rọ̀ tó f’ẹ́ni tó bá nínú tí ń rò oooo.

Ààrẹ Abdulkareem  Ajimatanraeje

Advertisements